By Highdee
Ọmọ ilé-ẹ̀kọ gíga
Bọ́síbí, o wá gbọ́
Tẹ́ láfíánu rẹ bẹ̀lẹ̀jẹ́
Kí o gbọ́ làbárè.
Ẹ̀kọ́ la ní o wá kọ́
Ohun mìíràn nìwọ ń yà sí
Bí o ti ń ṣe ìdánwò
Ni ò ń ṣángbó iṣẹ́, tí o ti fìdírẹmi
Ọdún mélòó lo fẹ́ ṣe èyí dà?
O ò rántí owó onírú, owó oníyọ̀,
Owó aláta, owó gbétan lé láńtà
Tí Baba tòun ti Yeye pawọ́pọ̀ gbà
Nítorí kí ìwọ lè jénìyàn láwùjọ
Ṣebí bí a bá fa gbùrù,
Gbùrù a máa fa igbó
Bí ó bá yẹ ọ́ lọ́la,
Ó di dandan kí o rántí àwọn òbí rẹ
Ìwọ ò bá tètè ronú kí o tó yan ọ̀rẹ́,
Mo ní kí o ronú dáadáa, kí o tó wọ ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́
Nítorí èrò lọbẹ̀ gbẹ̀gìrì…