By Khadeejah
Kókó leegun iyán .
Ṣùkù leegun àgbàdo.
Ká soro ká bàa bẹẹ .
Eegun òótọ́ ló jẹ́ .
Akọ̀wé akéwì , mo tún gbọ́’rọ̀ dé .
K’ẹyin ọdọ ó sún mọbi .
Ẹ sún mọbi kẹ́ gbálàyè ọ̀rọ̀
Ṣé ogun ‘ jára a rẹ ọ̀rẹ́ ‘ lo gbaye kan .
Èyí ni kò jẹ́ k’Ọ̀dọ́ ó mọ̀’wà á wù .
Gbogbo ọ̀dọ́ wá joyè ajáwéjura .
Wọ́n bọ́ra sí goloto , wọ́n ń pèé l’ọ́làjú .
Ǹjẹ́ ọ̀làjú rèé tàbí ọ̀yájú
‘Torí ẹ̀ ń ríran baba – ńlá wá á fín ni .
Ìran Yorùbá ò rìrìn òtòṣì rí
È é ti jẹ́ tẹ́ ẹ wá ń wọṣọ eṣùbèlèké kiri
A tiẹ̀ gbọ́ ti anímáṣaun obìnrin
A sì gbọ́ ti ọmọ òkú ọ̀run tí ń wọ àsíkà
Èwo ni ti ọmọ onílé ọlọ́nà tí ń rìn ìhòhò .
E jẹ́ lọ jáwọ́ nínú àpọ̀n tí kò yọ́ ,
Kẹ́ ẹ bomi ilá kaná .
K’ẹ́yin ọ̀dọ́ jáwọ́ rínrin ìhòhò àti wíwọ àkísà nírònà .
Tako tabo ọ̀dọ́ , ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ aṣọ tó múyán lórí . Nítorí ìrínisí ni ìsọ́nilọ́jọ̀